Ads

ÈFÈ NI EDE YORUBA PELU "OLUWADAMILARE_MPM" ATI "JOYCE"



  Toko tiyawo akuse kan n gbe ninu ilu kan nigba kan ri,,,,,, mukaila loruko oko n je ,,,,,wosila loruko iyawo re,,, oruko ko ro won rara,,,, tori won o la bee ni won o lu,,, ati rowo ki benu gan an iyen dogun,,,,won bi omokunrin mesan an ati omobinrin meje,,,,,, weda nise ti mukaila ko laaro ojo re, sugbon nigba ti nnkan dagun,,,, o fi oro na a se die omokunrin ko to,,,, Mukaila pelu  wosila  iyawo re ma a n lo segi loko etile pelu awon omo won mereerindinlogun,,, ki won o sa a le ri nnkan je,, eyi ko dede ri be e ,,,ise weda ko fi be e lo deede,,,, omo ni won si pa kale bi eda yii,,,, a a sa a jeun ni mukaila fi kotiju ta to fi ko iyawo atawon omo re gba oko igi sise lo,,,, bi won ba si ti ta igi yii,,,, owo ti won ba ri ni won fi n jeun,,,,koda nibi to buru fun won de,,, ahere ni won n gbe,,,, lai forogun lojo kan sa,,,, mukaila sun  n lo ba lalaa pe oun ri were kan to gbe eru lori laarin'ja tawon ti n lo tagi,,,, bi were na a ti taju kan to ri i ,,,, taara ona odo re lo mu pon,,,, bo si ti dodo re lo so eru ori re kale,,, owo ile okeere lorisirisi ,,,,dola,paunsi lo kunu apo ti were na a ru sori bamu bamu,,,,,,bi were ti gbe eru kale be e lo yise pada lo n lo,,,,bo ti n lo be e lo n kigbe mukaila apo ola re nu un o,,,, mukaila apo ola re nu un o,,,,  ko pe sigba yii ni mukaila taji ,,, 'ase ala ni mo tile n la',,,, beeni ero kan tun so si i lokan,,, o bere si ni da soro,,,, o ni ' hun-un-un,,,, eni rowo he loju ala to n dunnu ,,,, ko ya a tete tepa mose e ni o,,, afaije bee,,, ebi ni o lu u pa,,,,,eni ti ebi pa sun,,, loju ala re to je seku,,,, ibanuje ni,,,, nibi ti mukaila gbe n da so ni wosila iyawo re ti wole de,,,, 'baale mi,,, ki lo de te n da so bi oku ti o fomo saye lo? Mukaila ko o ro fun 'yawo re ohun to ri loju ala,,,,, iyawo re si gba a lamoran pe ko je ki awon tubo jara mose ,,,ati wipe owe loro Olorun,,, o le je pe ibi igi aseta yii naa lawon yoo ti la,,,,amo mukaila tun oro naa da ro o ni ohun a a se ku,,, n lo ba to awon agba omoran lo  ,,,, won ni inu oja na a ni ire re wa,,,,,

looto bo ti di owuro ojo kan ti mukaila ,wosila atawon omo won ru igi lo ta loja be e ni okunrin were kan dede yo ganboro lokan an kan,,, o gbe apo kan dani,,, owo korensi ile okeere lo kunu re pitimu,,, bo ti denu oja lo bere si ni pariwo,,,, mukaila, mukaila, mukaila, wa gba apo ola re lowo mi o, amo nnkan to wa seni ni kayeefi ni pe,,,, pelu ibinu ni were yii fi n soro,,, bee loju re si ranko,,,, o mu ada pana kan dani lowo otun re ,,niyen n ko mona mona,,, igbe aafewe,,, koju mo ribi gbogbo ara loogun e,,,, se e si mo pawon obinrin na a si lo kuku mo  on po n'nu oja tele,,,, ta lo fe ko ku ati pe ta ni yoo ko igiripa okunrin abugije toun tada pana to n ko mona mona lowo re loju,,, akanda eda gba a ,,,ni muraina were,,, o ga ni iwon ese bata mesan an,, o se firigban wale  be e ni,,,, o si san an gun,,,, bi gende sogoji won o to o mu,,,,,be e loju atilaawi tun n bena yeri yeri bi i toba koso,,, o ni lati je pe were yi i sese sagbo sara tan ni,,,, tori were ilu awon mukaila 
gan an ni kii sajeji were,,, gbogbo eeyan lo si mo wipe were yii gbona ju sanponna lo,,,, ko wa keni ti yoo sun mo were,,,, were o si yee pariwo ,,, mukaila ,,, mukaila ,,, mo ni ko o wa gbapo ola re lowo mi,,,,,   gbogbo awon eeyan ti sa tefetefe lo jinnajinna sibi ti were yii wa,,,, boja ba da,,, patepate ni o ku,,,,, mukaila atiyawo re wosila atawon omo gan an ti sa jinna ,,,,  won ta kete jinna rere,,,, abata ta kete bi eni ti o bodo tan,,,,jinnijinni bo won,,,,,amo ibi toro wa sogbon ko so were ko si ree o,,,,   wosila koju si mukaila oko re,,,, o ni 'baale mi, ala rere yin lo n se yii o, eni ti o si joyin inu apata ko ni wenu aake o,,,, pelupelu enu kinniun lowo wa o,,,,emi o ba ni kee kuku pakiti mole ,kee lo ko muraina were to kanju kanmu gbere towa wa yii loju o,,, eekan sa lomokunrin n ku,,, abi see fe ka ku sinu iya yii ni,,,, omo akin niyin e ko gbodo sojo,,,, beeni wosila kunle seki siwaju oko re,,, o bere si ni kii ni mesan an mewaa,,,, lo n pe,,,,' mukaila oko mi, olowo ori mi, eyin lomo ikoyi eso, omo eru ofa,,,ikoyi ti o riku sa, kini 'ku o firan baba re se,,, ikoyi kan o gbofa leyin ri,, gbagba iwaju ni baba yin fii gbota,,, eyi to gbofa leyin ojo lo se,,,, dakun baale mi ,,,sokan giri,,, maya le,,,, to muraina lo ko o lo gbapo owo re wa,,,,,,,eyin mukaila,emi wosila, la la la la lo kunnu oruko wa yii,,,ba a le rapo ola yii gba lowo muraina were,,, laala wa dopin ,,,, won si looko omo ni i ro omo,,,, e je kooko o ro wa,,, e tete lo gbapo ola wa lowo muraina ka le la,,,,,,, ka le lu,,,,,,

oro ree o,,,, e dakun bo ba seyin ni mukaila kin le o se?

Bo ba si je wosila leyin, iru amoran wo le o gba mukaila oko yin?

No comments

We love comments! We appreciate your queries but to protect from being spammed, all comments will be moderated by our human moderators. Read our full comment policy.
Copyright MediaPronounceNg Media. Permission to use quotations from this article is granted subject to appropriate credit being given to MPNG MEDIA as the source.
Lets enjoy a happy and meaningful conversation ahead!
For Inquiries/Tipoff/ADVERT PLACEMENT mail - benavatagencies@gmail.com or send us a message on our social media handles .
Please keep your comments clean always. Thank you!

WhatsupUnilorin.com. Powered by Blogger.